Ezekiel 19:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú, wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni. Wọ́n fi sí àtìmọ́lé, kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn fi ìkọ́ gbé e sínú ago, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Bábílónì, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Ísírẹ́lì.