Ezekiel 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, emi ran ọ si awọn ọmọ Israeli, si ọlọtẹ̀ orilẹ-ède, ti o ti ṣọtẹ si mi: awọn ati baba wọn ti ṣẹ̀ si mi titi di oni oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní-olónìí.