Ezekiel 2:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárin àwọn àkéekèé. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.