Ezekiel 20:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Síbẹ̀; ilé Ísírẹ́lì sọ̀tẹ̀ sí mí nínú ihà. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀-bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè è nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, ń ó sì pa wọ́n run nínú ihà.