Ezekiel 20:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé ń kò ní i mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.