Ezekiel 20:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mí mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú mi lórí wọn N ó sì mú kí ibínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni ihà.