Ezekiel 20:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nwọn kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn nwọn kẹgàn aṣẹ mi, nwọn si ti bà ọjọ isimi mi jẹ, oju wọn si wà lara oriṣa baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí pé wọn kò pa òfin mí mọ́, wọn sì tún kọ àsẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ọkàn wọn sì dúró ṣinṣin sọ́dọ̀ òrìṣà baba wọn.