Ezekiel 20:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti OLÚWA Ọlọ́run wí: Nínú èyí náà, baba yín ti sọ̀rọ̀ àìtọ́ sí mi nípa kíkọ mi sílẹ̀.