Ezekiel 20:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀.