Ezekiel 20:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Kini ibi giga ti ẹnyin nlọ na? Orukọ rẹ̀ ni a si npe ni Bama titi o fi di oni oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí?’ ” (Wọn sì ń pè ní Bámà di onì yìí.)