Ezekiel 20:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbà Ísírẹ́lì, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láàyè ní OLÚWA Ọlọ́run wí. N ò ní í gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’