Ezekiel 20:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wi fun ile Israeli pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; A bà nyin jẹ́ gẹgẹ bi baba nyin? ẹnyin si ṣe agbère gẹgẹ bi ohun-irira wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì: ‘Èyí ní ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí: Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?