Ezekiel 20:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nigbati ẹnyin nta ọrẹ nyin, nigbati ẹnyin mu ọmọ nyin kọja lãrin iná, ẹnyin fi oriṣa nyin bà ara nyin jẹ́, ani titi o fi di oni oloni: ẹnyin o ha si bere lọwọ mi, Iwọ ile Israeli? Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, irúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú wọn la iná kọjá-ẹ ń tèṣíwájú láti bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, èmi ó wa jẹ ki ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi bí ilé Ísírẹ́lì? Bí mo ti wà láàyè ní OLÚWA Ọlọ́run wí, N kò ní i jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.