Ezekiel 20:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, emi o si ṣà nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ka si, pẹlu ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ati pẹlu irúnu ti a dà jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú yín jáde láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni.