Ezekiel 20:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ṣà awọn ọlọ̀tẹ kuro lãrin nyin, ati awọn olurekọja, emi o mu wọn jade kuro ni ilẹ ti wọn gbe ṣe atipo, nwọn kì yio si wọ ilẹ Israeli: ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ṣa àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí mí kúrò láàrin yín. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọn ń gbé, síbẹ̀ wọn kò ní dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní OLÚWA.