Ezekiel 20:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lori oke mimọ́ mi, lori oke giga Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, nibẹ ni gbogbo ile Israeli, gbogbo wọn ni ilẹ na, yio sìn mi: nibẹ ni emi o gbà wọn, nibẹ ni emi o si bere ẹbọ nyin, ati ọrẹ akọso nyin, pẹlu ohun mimọ́ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Ísírẹ́lì, ni OLÚWA Ọlọ́run wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò sìn mí; n ó sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ ń ó bèèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín