Ezekiel 20:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o gbà nyin pẹlu õrùn didùn nyin, nigbati mo mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, ti mo si ko nyin jọ lati ilẹ gbogbo nibiti a gbe ti tú nyin ká si; a o si yà mi si mimọ́ ninu nyin niwaju awọn keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
N o tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín ká sí, ń ó sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin yín lójú àwọn orilẹ̀ èdè.