Ezekiel 20:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Ísírẹ́lì, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”