Ezekiel 20:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wi fun igbó gusù pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o da iná kan ninu rẹ, yio si jo olukuluku igi tutù ninu rẹ, ati olukuluku igi gbigbẹ: jijo ọwọ́ iná na ni a kì yio pa, ati gbogbo oju lati gusu de ariwa ni a o sun ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún igbo ìhà gúsù: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA. Èyí ní ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀ yóò sì jó olúkúlùkù igi tutu nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjí ọwọ́ iná náà kò ní i ṣe e pa, àti gbogbo ojú láti gúsù dé aríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.