Ezekiel 20:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí ó sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Ní ọjọ tí mo yàn Ísírẹ́lì, mo gbé ọwọ́ mi ṣokè nínú ẹ̀jẹ́ sí àwọn ọmọ ilé Jákọ́bù, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Éjíbítì, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.”