Ezekiel 20:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà mo lọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn pé ń ó mú wọn kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn ilẹ̀ yòókù.