Ezekiel 20:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ẹ̀ni kọ̀ọ̀kan yín mú àwọn àwòrán ìríra ti ẹ gbé ṣíwájú yín kúrò, kí ẹ sì má bára yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìsà Éjíbítì, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.”