Ezekiel 20:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n wọn sọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́ràn, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojú kọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Éjíbítì sílẹ̀, torí náà mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, ń ó sì jẹ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì.