Ezekiel 21:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́ Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún.