Ezekiel 21:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.