Ezekiel 21:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.