Ezekiel 21:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà èyíí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn.