Ezekiel 21:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí: ‘A ti fa idà yọ, láti paniyan. A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti awọn ara Ammoni, ati niti ẹgàn wọn; ani ki iwọ wipe, Idà na, idà na ti a fà yọ, a ti dán a fun pipa, lati parun lati kọ màna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!