Ezekiel 21:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ri ohun asan si ọ, nigbati nwọn fọ̀ àfọṣẹ eke si ọ, lati mu ọ wá si ọrùn awọn ti a pa, ti ẹni-buburu, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigbati aiṣedẽde pin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ jẹ́ pé a rì èké nípa yín àti àfọ̀sẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a yóò pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.