Ezekiel 21:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wi fun ilẹ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ ọ, emi o si fa idà mi yọ kuro li akọ̀ rẹ̀, emi o si ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó sì sọ fún un: ‘Èyí yìí ni OLÚWA sọ: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárin yín.