Ezekiel 21:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”