Ezekiel 22:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnìkínní ń bá aya ẹnìkejì rẹ̀ lòpọ̀; àwọn kan ń bá aya ọmọ wọn lòpọ̀; ẹ̀gbọ́n ń bá àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, àwọn mìíràn sì ń bá ọbàkan wọn lòpọ̀ ninu rẹ, Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.