Ezekiel 22:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti paniyan láàrin ìlú, wọ́n ń gba owó èlé, ẹ̀ ń ní àníkún, ẹ sì ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ aládùúgbò yín, ẹ ti gbàgbé mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; Ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìsòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé ẹ̀ mi; ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.