Ezekiel 22:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o fọ́n ọ ká sãrin awọn keferi, emi o si tú ọ ká si orilẹ-ède gbogbo, emi o si run ẽri rẹ kuro lara rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.