Ezekiel 22:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, ile Israeli di idarọ si mi: gbogbo wọn jẹ idẹ, ati tánganran, ati irin, ati ojé, lãrin ileru; ani nwọn jẹ idarọ fadaka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.