Ezekiel 22:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ìditẹ awọn wolĩ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, bi kiniun ti nke ramuramu ti nṣọdẹ; nwọn ti jẹ ọkàn run, nwọn ti kó ohun iṣura ati ohun iyebiye; nwọn ti sọ ọ̀pọlọpọ di opó fun u lãrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdìtẹ̀ sì wà láàrin àwọn ọmọ aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹ̀ran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìsúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀.