Ezekiel 22:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn wolĩ rẹ̀ ti fi ẹfun kùn wọn, nwọn nri asan, nwọn si nfọ afọ̀ṣẹ eke si wọn, wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, nigbati o ṣepe Oluwa kò sọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn wòlíì rẹ̀ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì iran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀sẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí’, nígbà tí ó ṣépè OLÚWA kò sọ̀rọ̀.