Ezekiel 22:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárin rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère,