Ezekiel 22:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si wá ẹnikan lãrin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibiti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi si wá ẹnìkan láàrin wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má báà parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan.