Ezekiel 22:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, iparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀ èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú.