Ezekiel 23:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria: àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ihamọra, tí wọn ń gun ẹṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn fanimọ́ra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Oun náà ní ìfẹ́kúùfẹ́ sí ará Ásíríà àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.