Ezekiel 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Babiloni bá tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bá a ṣeré ìfẹ́ lórí ibùsùn rẹ̀, wọ́n sì fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Bábílónì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ìbùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúùfẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.