Ezekiel 23:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ Aholiba, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi o gbe awọn olufẹ rẹ dide si ọ, lọdọ awọn ti ọkàn rẹ ti ṣi, emi o si mu wọn doju kọ ọ niha gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, Óhólíbà, báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà