Ezekiel 23:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo dojú kọ ọ́ láti ìhà àríwá, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọn óo gbógun tì ọ́ ní gbogbo ọ̀nà pẹlu apata, asà ati àkẹtẹ̀ ogun. N óo fi ìdájọ́ rẹ lé wọn lọ́wọ́, òfin ilẹ̀ wọn ni wọn óo sì tẹ̀lé tí wọn óo fi dá ọ lẹ́jọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si wá fi kẹkẹ́ ogun, kẹkẹ́ ẹrù, ati kekẹ́ kekeke doju kọ ọ, ati pẹlu ìgbajọ ọ̀pọ enia, awọn ti yio doju asà, ati apata, ati akoro kọ ọ niha gbogbo: emi o si gbe idajọ kalẹ niwaju wọn, nwọn o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi idajọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò wa dojú kọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú àṣà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àsíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.