Ezekiel 23:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si doju owu mi kọ ọ, nwọn o si fi irúnu ba ọ lò: nwọn o fá imu rẹ ati eti rẹ; ati awọn ti o kù ninu rẹ yio ti ọwọ́ idà ṣubu: nwọn o mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin lọ, ati awọn ti o kù ninu rẹ, li a o fi iná run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunnú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn ètí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jó run.