Ezekiel 23:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li emi o jẹ ki ifẹkufẹ rẹ mọ kuro lọdọ rẹ, ati panṣaga rẹ ti o mu ti ilẹ Egipti wá; tobẹ̃, ti iwọ kì yio gboju rẹ soke si wọn, bẹ̃ni iwọ kì yio si ranti Egipti mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Éjíbítì. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú aáyun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Éjíbítì mọ.