Ezekiel 23:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ọ le awọn ti iwọ korira lọwọ, li ọwọ́ awọn ẹniti ọkàn rẹ ṣi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó korìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti sí kúrò.