Ezekiel 23:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si ba ọ lo ilo irira, nwọn o si ko gbogbo iṣẹ rẹ lọ, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho ati ni goloto: ati ihoho panṣaga rẹ li a o tu silẹ, ti ifẹkufẹ rẹ, ati panṣaga rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìdàrúdàpọ̀ rẹ