Ezekiel 23:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní: “ọpọlọpọ ìyà tí mo fi jẹ ẹ̀gbọ́n rẹ ni n óo fi jẹ ọ́, wọn óo fi ọ́ rẹ́rìn-ín, wọn óo sì fi ọ́ ṣẹ̀sín, nítorí ìyà náà óo pọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ o mu ninu ago ẹ̀gbọn rẹ ti o jin, ti o si tobi: a o fi ọ rẹrin ẹlẹya, a o yọ ṣuti si ọ; o gbà pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè: “Ìwọ yóò mu nínú aago ẹ̀gbọ́n rẹ, aago tí ó tóbi tí ó sì jinnú: yóò mú ìfisẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí aago náà gba nǹkan púpọ̀.