Ezekiel 23:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan ṣé o óo dá ẹjọ́ Ohola ati Oholiba? Nítorí náà fi ìwà ìríra tí wọ́n hù hàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Óhólà àti Óhólíbà? Nítorí náà dojú kọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,